AYO OLUKOTUN: MO GBỌ́ OHÙN RẸ NÍNÚ AFẸ́FẸ́

Nigeriacurrent
Nigeriacurrent

By Toyin Falola

Ẹmọ́ kú, ojú òpó dí

Àfèrèmọ̀jò kú, ẹnu ìṣà ń ṣọ̀fọ̀

Ọ́pálámbá ọtí eèbọ̀ fọ́, Onígbàsọ ò ri sọ̀

Olukotun lọ, n ò ri mọ́.

Ìwọ Òrẹ́ mi lọ láì wẹ̀yìn wò

Ọjọ́ mẹ́jìlá d’ógún, ó dà bí òní.

Mo gbọ́ ohùn rẹ nínú afẹ́fẹ́,

Mo rí ẹ̀rù rẹ nínú ojú omi.

Ó dà bíi pé o wà ní ibì kan nítòsí,

Níbi tí ìwọ kò le fi ọwọ́ kàn mi.

Ayé ń yí, ó ń bọ̀, ó ń lọ,

Ṣùgbọ́n iranti rẹ̀ kò fọwọ́ sọ.

Orí mi kún fún ìranti rẹ,

Ọkàn mi sì kún fún ìdárò rẹ pẹ̀lú.

A jọ d’órí omi ayé,

A fi ìfẹ́ rọ̀ mọ́ra.

Ṣùgbọ́n ayé kì í gbà láéláé,

Ó mú ọ lọ, ó fi ọgbẹ́ sọ́kàn

Àràbà ya níjù

Ẹja ńlá lọ lómi.

Mo wá máa sọ̀rọ̀ sí afẹ́fẹ́,

Kí ó gbóhùn mi dé ọ̀dọ̀ rẹ

Ojú rẹ wá di

Ohun mò ń gbé inú àwòrán wò

Haa, igi oko dá

Ẹyẹ oko ti gbéra sọ.

Òrẹ́ mi, ìwọ t’ó lọ,

Ìrántí rẹ̀ kò ní ṣí fún mi.

Mo máa rántí ọ nínú ìrọ̀lẹ̀,

Nígbà tí ìmọ́lẹ̀ òòrùn bá n rẹ̀wà

Nígbà tí ọjọ́ bá kanri

Ìrántí rẹ dúró ṣinṣin.

Sùn-un re

Ní ilé ayé tí kò ní ikù.

Ṣùgbọ́n má gbàgbé mí, òrẹ́ mi,

Tí mo bá dé, jọ̀wọ́, ṣe mi káàbọ̀.

Káa tó rí Erin, ó di igbó

Káa tó rí Ẹ̀fọ̀n, ó di ọ̀dàn

Káa tó rí Lèkélèké ẹyẹ oòṣà ńlá

Ó di dandan kaa délé ẹfun

Ó di gbéré

Ó di bí ẹni bá jọ ni

Ìpàdé di ọjọ́ ìkẹyìn

Ìpàdé di ọjọ́ ìdájọ́ ńlá.

Please join us at the inaugural Professor Olukotun’s memorial lecture at Lead City University on Tuesday, March 18, 2025, at 10.30 AM.

Share This Article
Leave a Comment

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *